Tuesday, 16 January 2018

ODUN TITU



*ODUN TITUN*

Lati ojo kinni osu kinni odun 2018 lawon eeyan ti n kira won ku odun titun. Aimoye ateranse,ikinni lori redio,telifisan,iwe iroyin ati lori ero ayelujara. Amo ibeere to ye ka bi ara wa ni pe NJE ODUN TITUN WA??

Ka to le dahun ibeere yen. O ye ka koko mo ohun ti a n pe ni odun. Odun ni saa iwon akoko tawon eeyan yan kale fun ara won. Atigba ta laye si ti daye ni won ti n ka odun. Ohun mi to ye ka tun mo ni itumo gbolohun ede yoruba naa "TITUN"
Bi yoruba ba so pe nkan titun. Ohun to tumo si ni pe ohun naa yato patapata si ti tele. Tabi ka sope ohun ti ko ti waye ri towa sese sele. Apeere ni alaboyun to sese bimo. Bi yoruba ba maa ki omo naa kabo,ohun ti won saba maa n so ni pe "kabo omo titun alejo aye" tori pe igba akoko ta o ri omo naa niyen. 
Ka ma f'opa polopolo p'ejo. Ba ba sope odun tuntun pelu itumo gbolohun ede yoruba naa "tuntun" a je pe ohun ta n so nipe ohun tuntun ara oto ni odun naa je. Ki la si fi nka odun bi ko se bi ojumo se n mo tile n su. Ti oorun n ran,ti ojo si n ro,ti osupa n ran loju sanman lale ti irawo si n tan imole. Bi ooru se n mu ti otutu si n mu. Ko sisi ohun to tuntun ninu ona ti awon nkan yii n gba sele yato si ti odun to koja. Kiwa lo tuntun ninu odun nigba naa?
Bi ohun kan bawa to ye ko tuntun ninu odun. Ko ye ko ju iwa wa,isesi wa ati ona igba ronu wa lo. Tori eyi ni yoo pinnu iru eni ta a je.

Amo o ku ni ibon n ro. Ibeere kan si seku sile. KINI IDI TA FI N KA ODUN??
Idahun si ibeere yii o loju po,bee naa ni ko dinu. Gbogbo onikakaye eda lo ye ko le dahun ibeere naa. Enikan so pe idi ta fi n ka odun ni lati mo iye ojo ori wa. Ododo oro niyen. Amo ta ba ni ka so oro naa ni sako. Idi ta fi n ka odun ni lati mo igba ati asiko ti ohun kan sele. I ba je ohun rere abi odikeji re( laabi o ni kangun sodo wa o)

*Aremo jah_akewi*

#onkorin
#onkotan
#akewi

+2348170981831
+2348109407587

Thursday, 27 April 2017

ITAN ORILE: ILU ILORIN

                                  (ITAN ILORIN)

Oju mi ti ri to ninu itan eti mi si ti gbo to ninu iwadi ijinle debi pe eru ohun to le sele lehin ti awa ti a nbe laye ni saa yi ba lo tan nba mi nitori a nso nipa itan awon eni ana bawo ni Itan yio se so nipa ti wa gan. 
Loni awuyewuye po lori ilu Ilorin Looto ni itan Ilorin ko fi be ru'ju sugbon ase ilu ti bo lowo awon omo onile to si je pe Iran ajeji lo nje Emir nibe loni, sugbon mo fe ka mo pe lara ilu ti itan won je ogbé okàn fun awon opitan ni ilu Ilorin wa. 

LADERIN LO TE ILU ILORIN 

Awon opitan gba pe omo bibi Oyo Alafin ni Laderin sugbon ironu mi pin yeleyele lori itumo Laderin yala Oladerin ti won pa ìró je ti yio wa je Ola-dode-erin ti o ba je Oladodeerin ni a je pe omo ola ni Laderin ni Ilu Oyo sugbon to ba je pe Laderin ti o tun lo ba bayi ni Ola-di-erin iyen nipe ola di erin Yorùbá mo nso oruko eniyan mo eranko tabi igi ati odo lati le saponle eniyan tabi idile kan, to ba je oladierin ni omo ola ni loyo ti won si juwe ola awon dabi ti erin nitori Yorùbá a ma ni erin nsola ninu igbo nitori ohun ni eranko to tobi ju. 
Laderin je ode ati akoni sugbon kiise eso nitori omo ola Òyó ni kiise abuku ka ni awon omo Oba Òyó nse ode tabi awon omo Oyo Mesi nitori kosi eni ti ki da oko nile Yoruba yala idile Oba ko ba je Akeyo (Prince of Oyo) be sini anfani wa fun won lati se ode nitori won mo nse owo lati ilu kan si ekeji tabi si awon orilede iru eyi ti Aole se lo ilu Apomu lorilede Owu si Ife saaju ko to di Oba. 
Yoruba ni eni ti yio pa erin ko to ju egbe eyi yio je ka mo pe ki se ode lasan ni yio pa erin ogbologbo ode ni, lara ogbologbo yi ni Laderin wa, ohun oju ode ri ni iju won ki dele wi nitori won mo npé ninu igbe ode, ninu igbe ode yi na ni won tun mo npago si lati le mo ko nkan isura si ati lati mo sun pelu awon ode tun mo npade nibe ti eyi yio si je ki awon ode mo iyeju awon ode akoni to wa sode ni agbegbe na. 
Iwadi je ka mo pe ibi ti Laderin pago si yi ni okuta kan wa to ti mo nlo ada, obe ati ida re ti won fi irin se ti awon ode to nwa sodo re na mo nlo ada won nibe, awon ode na ipago tiwon nitori ahehe ni won nko a ko le so boya ibe ni Laderin ba oluta yi tabi oun lo yi wa ibe sugbon okuta yi gbajumo larin awon ode latari pe o mo nlo irin won mu dada, a nlo lo irin lodo Laderin lo di Ilorin tabi ka ni esi ibere pe kini o nfi okuta to wa niwaju ago ode re se to si dahun pe ilorin ni lo mu oruko Ilorin waye okuta ti Laderin nfi irin lo lo nje Ilorin. 
Diedie awon ode npo si ninu igbe ode iwa ooto ati akoni Laderin je ki awon ode mo wari fun ti opo awon to si wa ra eran igbe ati èyà ara erin si njoko de lasiko to ba se ode lo nigbati o kiyesi eyi o pago to je ile elewe bi meta si ki awon eniyan le mo ri aye sun papa oju ona ero ni ago Laderin wa nikehin opo awon ode ko ago won sile won si lo ipago tuntun si odo Laderin, niwon igba to je omo Ola ni Loyo kosi ewu fun lati pago tabi so ago ode di abà nitori ola ni nse be ni. 
Kere kere awon eniyan bere si po ni aba Laderin be ni aba di abule ti abule si di Ileto, Lasiko ti Laderin fi ndabira awon obi re wa ni Oyo inu Òyó na won si ku ti won si sin won si lehin iku awon obi re opinu lati so Ilorin di ile o si gba ase lowo Alafin pelu adehun sisan isakole, Laderin ni Bale Ilorin akoko emi re gun dada ko to ku sugbon Ileto ti ile ibe ko ju bi ogun pere lo fi Ilorin si ile ewe sini pelu.

ORIKI ILU: ILARO

ORIKI ILARO
Eji ogogo omo iku lodo toti deri'lewa
Omo adiye sun won sebi kuku loku, kiwon to lotatan adiye dide oyan fanda
Ilaro omo erin lonibu omo efon lo nona
Omo pakan lakan leyin jijo awo ni gbori ile omo ina tin jo geregere lori omi
Ilaro omo aran o sunwon e ko nigbale omo oku eko omo ijagudu akara
Ogogo omo e ba oro omo ina esan ogbo jinijinji ama jo’le gerege
Ogogo tin yini lokun lapa omo oku dudu ti koya kunran
Omo kulodo to tideri’lewa omo kinikan o joye lesa, tobawa joye lesa nko ilesanmi lasan loba yin muwon je.
Ogogo lomo agbele jebu, omo yiyo lanyo nile baba tobiyin lomo
Ilaro omo ku la ngberi omo kulodo ao ki wan kuloko tan won di apon
Otojo kotojo tomo kulodo nbo lati oko egan loba pade omi sonte, egbon mu aburo na mu gbogbo eni tomu sonte lomu rogbo dan

ISEBAYE:ORIKI ESU LALU

                                                                 ( ORIKI ESU)
**Oriki Esu**
Esu, Esu Odara, Esu laalu ogiri oko.
Okunrin ori ita,
a jo langa langa laalu
A rin lanja lanja lalu.
Ode ibi ija de mole.
Ija ni otaru ba d’ele ife.
To fi de omo won.
Oro Esu, to to to akoni.
Ao fi ida re lale.
Esu ma se mi o
Omo elomiran ni ko lo se.
Pa ado asubi da.
Na ado asure si wa
Laaroye,
Adijaale takete
Baba orita
A fi'bi dire, a fire dibi
Ma se mi o
Ma so beeni mi di beeko
Ma so beeko mi di beeni
Ojowu okunrin
Laaroye ogiri oko
**Awa ti mo oriki esu, ki esu mase wa o**

ORIKI ILU:EFON ALAYE

                              ( ORIKI ILU EFON ALAYE)

EFON ALAAYE
1. Efon npele omo oloke
Oke - ko ma ‘Laye tile ogun
Edu Ule Ahun Efon kumoye
Lomode lagba lule loko
Ibi an bini na se
In mo mo gbagbe Ule
Efon - Eye o la ke le Efon
Olorun laba ri a.
Efon npele omo oloke,
Edu Ule Ahun Efon kumoye
2. Oba Laye l'Efon,
Uwarafa mefa kete,
Indi Efon mu gbonin - gbonin
Akanda Ulu Olodumare
Afefe ibeo tuni lara
Omi ibe a mu fokan bale ni
Un kejarun, o jina s'Efon.
Efon npele omo oloke
Edu Ule Ahun Efon kumoye.
3. Iyo l'Efon re lau jo ero
Un da an da an mani
Aaye, Obalu, Ejigan, Emo,
Usaja, Ukagbe, Usokan
Efon in dimu gbonin-gbonin
Efon npele omo oloke
Edu Ule Ahun Efon kumoye



CONTACT US

YOU CAN CONTACT US ON THIS PLATFORM FOR ANY SUGGESTION OR ADDITIONAL PACKAGE.
ON FACEBOOK>FACEBOOK.COM/ASATIWATIWA
ON WHATSAPP>08136000037
ON EMAIL>AKEWITUNU@GMAIL.COM
FOR LIVE CALIING>08136000037/08163558827

ORIKI ILU: EKO

                                        EKO/LAGOS


Eko Akete Ile Ogbon
Eko Aromi sa legbe legbe
Eko aro sese maja
Eko akete ilu okun alagbalugbu omi,
Ta lo ni elomi l'eko? ebiwon pe talo ni abatabutu baba omikomi, talo laabata buutu baba odo kodo
Eko adele ti angere nsare ju eniyan elese meji lo
Eni to o ba lo si ilu eko tiko ba gbon, Koda, bo lo si ilu oyinbo ko legbon mo
Afefe toni pon wa ni bebe okun ti yin, faaji to ni pan wa ni bebe osa
Eko omo osha nio ose, mase kutere, osha n gbobi, kutere n gbori
Eyin lomo afinju woja marin gbendeke, obun woja n wapa sio sio
Eyo o Aye'le Eyo o, Eyo baba n teyin to n fi golu n sere, eyin oni sanwo onibode, odilee
Ti oju o ba ti ehin igbeti, oju o ni t'eko le