Showing posts with label ISEBAYE. Show all posts
Showing posts with label ISEBAYE. Show all posts

Thursday, 27 April 2017

ISEBAYE:ORIKI ESU LALU

                                                                 ( ORIKI ESU)
**Oriki Esu**
Esu, Esu Odara, Esu laalu ogiri oko.
Okunrin ori ita,
a jo langa langa laalu
A rin lanja lanja lalu.
Ode ibi ija de mole.
Ija ni otaru ba d’ele ife.
To fi de omo won.
Oro Esu, to to to akoni.
Ao fi ida re lale.
Esu ma se mi o
Omo elomiran ni ko lo se.
Pa ado asubi da.
Na ado asure si wa
Laaroye,
Adijaale takete
Baba orita
A fi'bi dire, a fire dibi
Ma se mi o
Ma so beeni mi di beeko
Ma so beeko mi di beeni
Ojowu okunrin
Laaroye ogiri oko
**Awa ti mo oriki esu, ki esu mase wa o**

Monday, 24 April 2017

ISEBAYE: IWE LAILAI


Nijọwo ni ao bọ lọwọ agbọnrin eṣi ti a njẹ lọbẹ ninu awọn iwe ti awọn ọmọ ile iwe fi nkọ ẹkọ. Nko sọ wipe awọn iwe atijọ ko dara ṣugbọn koye ki awọn iwe wọnyi jẹ iwe gbogi ti awọn ọmọ wa yio maa ka lode oni.
Njẹ ẹ mọ wipe;
” Bade ṣi nde ade”
”Alade ṣi wu iho lori”
“Iyan ṣi n funfun nẹnẹ”
Njẹ bawo ni aṣe fẹẹ dagba soke nigbati o jẹ wipe iwe ti baba mi ka ni mo ka, oun si ni Tiwatọpẹ ọmọ mi nmura lati ka laipẹ. Ti a ba wo iwe wọnyi ayipada ranpẹ lo wa ninu wọn.
Ẹjọwọ ẹ bawa sọ fun awọn ijọba wa wipe ki wọn sọ fun onibọn oje ko gbe ibọn rẹ pamọ ki Alawiye sinmi awuyewuye ẹjọ, kiwọn fun awọn iwe ode oni ti o ba igba mu laye ki o goke agba nitori aṣọ igba ni a nda fun igba ooo, ki a ma ba maa fi akisa ṣe aṣọ wọ.
YOOBA DUN!
OYIN NI!

ISEBAYE:ITUMO EDE YORUBA


Oriṣi Ọna Ti A Le Gba Gbe Ede Tabi Ohun Jade.
1. Arangbọ.
2. Isare.
3. Orin.
Arangbọ: Ni ilana igbohun tabi igbede jade ti yoo ni itumọ si olugbọ, arangbọ yii ni a maa n lo lati fi gbe awọn nnkan wọn yii jade bii Alọ Pipa, Arọ Jija, Owe Pipa, Ọfọ Pipe, Ayajọ Pipe, Igede ati bẹẹbẹ lọ.
Isare: Maa n ni igbohun soke ati igbohun sodo tabi igbohun walẹ pupọ ju nitori pe isare ni ilana gbigbe ohun tabi ede jade si olugbọ ti yoo sini itumọ ni kikun, isare maa n jẹmọ ilana ẹkọsẹ nitori pe ko dabi Owe, Alọ, Arọ, Ọfọ ti eniyan lee ma maa ṣe lami kọ. Isare ni ọna ti a ngba lo ohun nipa gbigbe awọn nnkan yii jade bii Ijala, Ẹkun Iyawo, Iremọje, Iwi Egungun, Ẹsa Egungun, Iyẹrẹ Ifa, Ewi, Ẹgẹ Dida, Rara Sisun ati bẹẹ bẹ lọ.
ORIṢI ISARE.
1. Isare Ajẹmọ Ẹsin.
2. Isare Ajẹmọ Ayẹyẹ.
Orin: yatosi awọn mejeeji yii, bi o tilẹ jẹ pe ṣekuṣẹiyẹ ni orin jẹ, orin a maa jẹ jade lati inu arangbọ ati isare, orin naa maa n ni iwọwun ti a mọ si igbohun soke ati gbigbe ohun walẹ tabi odo, koda ti eniyan ko bani ohun to jina tabi toye kooro, ko lee kọrin daada, orin a maa ni dida ti a mọ si lile ati gbigbe ninu, ẹbun si tun ni orin jẹ, ẹni ti Eledua ba fun ni.
Orin a maa ni arangbọ, bẹẹ arangbọ naa a maa wa ninu orin, ko si ibi ti a ko ti le kọnrin ni ilẹ Yooba.
ORIṢI ORIN.
1. Orin Ajẹmọ Ẹsin.
2. Orin Ajẹmọ Ayẹyẹ.
ORUKỌ AWỌN ORIN NI ILẸ YOOBA.
Orin Ọmọ, Orin Igbeyawo, Orin Iṣile, Orin Awada, Orin Aṣa, Orin Alufaṣa, Orin Oku, Orin Baluu, Orin Ogodo, Orin Gẹlẹdẹ, Orin(Ṣẹkẹrẹ) Agbe, Orin Obitun, Orin Dadakuada, Orin Olele, Orin Etiyẹri, Orin Alamọ, Orin Juju, Orin Ege Dida, Orin Pakenki, Orin Panṣẹkẹ, Orin Alemọ, Orin Alamọ, Orin Waka, Orin Bọlọjọ, Orin Awurebe, Orin Ṣajẹ, Orin Fuji, Orin Awọn Oriṣa Bii Ifa, Ṣango, Ọṣun, Ọya, Eṣu, Yemọja, Ogun, Ẹgbẹ ati bẹẹ bẹ lọ.
Ao maa tẹsiwaju pẹlu akori miran lọla. Eku Ikale Sa/Ma.
YOOBA DUN!
OYIN NI!

Saturday, 22 April 2017

ISEBAYE: ITAN ODUDUWA

                                       ITAN ODUDUWA

Odùduwà Bí abá porí akoni, áafidà halè gààràgà, táabá porí èya Yorùbá, dandan ni kí á sòrò débi eni tó jé babańlá won, Ìyen Odùduwà á tìe wòrò.
Ìtàn méjì gbógì ló sòrò tó seé gbámú nípa ibi tí Odùduwà ti wá, àkókó ìtàn náà ni ìtàn tó sórò nípa tí Odùduwà se wá láti wáá gba isé tí Olódùmarè kókó rán Obàtálá se.
Olódùmarè fún Oduduwa ní àwon nìkan máàmú ken, èyí tó mú wá láti wáá lo, ómú èwòn wá èyí tó fi rò wá, àti àkùko adìye èyí tó tan yèpè tó mú wá kálè, tí ìyàngbe ilè fi jáde.
Ó wá mú ìgbá dání, èyí tó gbìn àti alágemo tó lo wòó bóyá ilè náà ti gbe.
Ó dùduwà yìí ló wá dásèé gbogbo èdá tó wà lórí ilè ayé, ibi tó sì rò sí ni Ilé-Ifè, Ibi tí wón so pé ojúmó ti ń mó wá.
Nítóri náà, gégé bíi ìtàn yìí se so, Odùduwà kìíníkàn ńse bàbá ńlá Yorùbá nìkan, Sùgbón bàbá ńlá gbogbo aráyé, nígbà tí Ifè kìí níkàn ńse orírun Yorùbá nìkan, sùgbón orísun gbogbo èdá.
Ìtàn lejì so pé Mékà ni eni tí a mò sí Odùduwà ti wá, ìwà ìbòrìsà reè sì ló gbée kúrò ní Mékà.
Ìtàn yìí so pé Ìjà bé sílè láàrín-ín àwon elésìn musùlùmí àti àwon abòrìsà, ti Odùduwà je olórí won, inú ìjà yìí ni Lámúrúdu, eni tí ó jé bàbá Odùduwà kú sí, èyìn èyí ni Odùduwà gbéra kúrò ní Mékà tó sì wá tèdó sí Ilé-Ifè.
Ìtàn fi yé wa pé, Odùduwà bá àwon ènìyàn kan ní Ile-Ifè, àwon ènìyàn yìí ni Odùduwà bá fìjà peéta, tí ó sì borí won nígbèyìn gbéyìn ó bo rí won, ó sì wáá doba won.
Ìtàn yìí jé kí á mò wípé odùduwà ló mú ètò ìsàláóso wá sí Ilé-Ifè, èyí tó gbé wá láti ìlú Mékà.
Nígbà tí Odùduwà dàgbà títí ó wà fún àwon omo rè ní ade, ósì fún àwon kan ní ìlèkè. Àwon omo Odùduwà wònyín ló te àwon ìlú dó káàkiri ilè Yorùbá.

Friday, 21 April 2017

ISEBAYE: ODU IFA

                                          IFA


Looto ni mi o batan sugbon mo baroba, aroba ti a n soro re yii ni baba itan.
Ni ilana ati waye Yooba, awon babanla wa gbagbo ninu ohun ti won n pe ni "Eleri'pin" Eleri'pin je oro ti a tun le e lo lati fi sapejuwe ifa.
Layejohun, kii won to le e dawo le ohunkohun, ifa je atona, ati alasotele ohun ti o ti sele, ohun to n sele lowolowo ati ohum ti yio sele lojowaju bopeboya. Abajo to fi je wipe bii won ba bi omo nigbana, won a beere lowo ifa awon ohun eewo, iru ise ti omo bee yio se bi o ba dagba ati ese ifa to gbe waye.
Ifa kii bale ko maa so ohun kan, boya ko yan ebo, etutu, nigba miran ewe ko la awon ona abayo kale leyi to seese ko ma a romo ebo tabi etutu.
Awon to je olusin ifa gbagbo pe ifa ki i paro, opele kii si seke, babalawo to ba so ohun ti ifa ko wi, aso iru eni bee maa n pon ni. Eyi lo je ki a maa rii awon alawo ti won o se fowo ro ti seyin lawujo.
Wonyi lawon ODU IFA merindinlogun ti o wa:
1). Èjì Ogbè
2). Öyëkú Méjì
3). Ìwòrì Méjì
4). Òdí Méjì
5). Ìrosùn Méjì
6). Öwônrín Méjì
7). Öbàrà Méjì
8). Ökànràn Méjì
9). Ògúndá Méjì
10). Ösá Méjì
11). Ìká Méji
12). Òtúúrúpön Méjì
13). Òtùá Méjì
14). Ìretë Méjì
15). Ösê Méjì
16). Òfún Méjì.
Awon ODU IFA kookan lo ni ESE IFA tire. A o maa soro lojo miran lori ESE IFA bakanna. Ejowo o, mi o ki n se omo onifa o, iwadi ati isese lo mu mi gun oro toni o.*erin*
.
.
.
YOOBA DUN!!!