Monday, 24 April 2017

ISEBAYE:ITUMO EDE YORUBA


Oriṣi Ọna Ti A Le Gba Gbe Ede Tabi Ohun Jade.
1. Arangbọ.
2. Isare.
3. Orin.
Arangbọ: Ni ilana igbohun tabi igbede jade ti yoo ni itumọ si olugbọ, arangbọ yii ni a maa n lo lati fi gbe awọn nnkan wọn yii jade bii Alọ Pipa, Arọ Jija, Owe Pipa, Ọfọ Pipe, Ayajọ Pipe, Igede ati bẹẹbẹ lọ.
Isare: Maa n ni igbohun soke ati igbohun sodo tabi igbohun walẹ pupọ ju nitori pe isare ni ilana gbigbe ohun tabi ede jade si olugbọ ti yoo sini itumọ ni kikun, isare maa n jẹmọ ilana ẹkọsẹ nitori pe ko dabi Owe, Alọ, Arọ, Ọfọ ti eniyan lee ma maa ṣe lami kọ. Isare ni ọna ti a ngba lo ohun nipa gbigbe awọn nnkan yii jade bii Ijala, Ẹkun Iyawo, Iremọje, Iwi Egungun, Ẹsa Egungun, Iyẹrẹ Ifa, Ewi, Ẹgẹ Dida, Rara Sisun ati bẹẹ bẹ lọ.
ORIṢI ISARE.
1. Isare Ajẹmọ Ẹsin.
2. Isare Ajẹmọ Ayẹyẹ.
Orin: yatosi awọn mejeeji yii, bi o tilẹ jẹ pe ṣekuṣẹiyẹ ni orin jẹ, orin a maa jẹ jade lati inu arangbọ ati isare, orin naa maa n ni iwọwun ti a mọ si igbohun soke ati gbigbe ohun walẹ tabi odo, koda ti eniyan ko bani ohun to jina tabi toye kooro, ko lee kọrin daada, orin a maa ni dida ti a mọ si lile ati gbigbe ninu, ẹbun si tun ni orin jẹ, ẹni ti Eledua ba fun ni.
Orin a maa ni arangbọ, bẹẹ arangbọ naa a maa wa ninu orin, ko si ibi ti a ko ti le kọnrin ni ilẹ Yooba.
ORIṢI ORIN.
1. Orin Ajẹmọ Ẹsin.
2. Orin Ajẹmọ Ayẹyẹ.
ORUKỌ AWỌN ORIN NI ILẸ YOOBA.
Orin Ọmọ, Orin Igbeyawo, Orin Iṣile, Orin Awada, Orin Aṣa, Orin Alufaṣa, Orin Oku, Orin Baluu, Orin Ogodo, Orin Gẹlẹdẹ, Orin(Ṣẹkẹrẹ) Agbe, Orin Obitun, Orin Dadakuada, Orin Olele, Orin Etiyẹri, Orin Alamọ, Orin Juju, Orin Ege Dida, Orin Pakenki, Orin Panṣẹkẹ, Orin Alemọ, Orin Alamọ, Orin Waka, Orin Bọlọjọ, Orin Awurebe, Orin Ṣajẹ, Orin Fuji, Orin Awọn Oriṣa Bii Ifa, Ṣango, Ọṣun, Ọya, Eṣu, Yemọja, Ogun, Ẹgbẹ ati bẹẹ bẹ lọ.
Ao maa tẹsiwaju pẹlu akori miran lọla. Eku Ikale Sa/Ma.
YOOBA DUN!
OYIN NI!

0 comments:

Post a Comment