Showing posts with label EWI. Show all posts
Showing posts with label EWI. Show all posts

Tuesday, 16 January 2018

ODUN TITU



*ODUN TITUN*

Lati ojo kinni osu kinni odun 2018 lawon eeyan ti n kira won ku odun titun. Aimoye ateranse,ikinni lori redio,telifisan,iwe iroyin ati lori ero ayelujara. Amo ibeere to ye ka bi ara wa ni pe NJE ODUN TITUN WA??

Ka to le dahun ibeere yen. O ye ka koko mo ohun ti a n pe ni odun. Odun ni saa iwon akoko tawon eeyan yan kale fun ara won. Atigba ta laye si ti daye ni won ti n ka odun. Ohun mi to ye ka tun mo ni itumo gbolohun ede yoruba naa "TITUN"
Bi yoruba ba so pe nkan titun. Ohun to tumo si ni pe ohun naa yato patapata si ti tele. Tabi ka sope ohun ti ko ti waye ri towa sese sele. Apeere ni alaboyun to sese bimo. Bi yoruba ba maa ki omo naa kabo,ohun ti won saba maa n so ni pe "kabo omo titun alejo aye" tori pe igba akoko ta o ri omo naa niyen. 
Ka ma f'opa polopolo p'ejo. Ba ba sope odun tuntun pelu itumo gbolohun ede yoruba naa "tuntun" a je pe ohun ta n so nipe ohun tuntun ara oto ni odun naa je. Ki la si fi nka odun bi ko se bi ojumo se n mo tile n su. Ti oorun n ran,ti ojo si n ro,ti osupa n ran loju sanman lale ti irawo si n tan imole. Bi ooru se n mu ti otutu si n mu. Ko sisi ohun to tuntun ninu ona ti awon nkan yii n gba sele yato si ti odun to koja. Kiwa lo tuntun ninu odun nigba naa?
Bi ohun kan bawa to ye ko tuntun ninu odun. Ko ye ko ju iwa wa,isesi wa ati ona igba ronu wa lo. Tori eyi ni yoo pinnu iru eni ta a je.

Amo o ku ni ibon n ro. Ibeere kan si seku sile. KINI IDI TA FI N KA ODUN??
Idahun si ibeere yii o loju po,bee naa ni ko dinu. Gbogbo onikakaye eda lo ye ko le dahun ibeere naa. Enikan so pe idi ta fi n ka odun ni lati mo iye ojo ori wa. Ododo oro niyen. Amo ta ba ni ka so oro naa ni sako. Idi ta fi n ka odun ni lati mo igba ati asiko ti ohun kan sele. I ba je ohun rere abi odikeji re( laabi o ni kangun sodo wa o)

*Aremo jah_akewi*

#onkorin
#onkotan
#akewi

+2348170981831
+2348109407587

Tuesday, 25 April 2017

EWI: OLOMO LO LAYE

                                          (OMO)

OLOMO LO LAIYE
EDUMARE WA FUN WA LOMO AMUSEYE
OMO TII TOJU ARA
TII TOJU ILE
TII TOJU BABA
FUN WA LOMO ATATA
TII MUNU IYA DUN.

OMO TITUN TO WA SILE AIYE
OBI ORE ATOJULUMO
E MA KU ALEJO OMO TITUN
OROGBO LO NI KOO GBO SAIYE
KOO GBO PELU DERA.

OMO OWO KII KU LOJU OWO
BEE NI OMO ESE KII KU LOJU ESE
OMO WA O NII KU
TIYIN NAA O NI DAGBEGBIN BI ISU

ODOODUN LA NROROGBO
ODOODUN LA NRAWUSA
ODOODUN LA NROMO OBI LORI ATE
LODUNLODUN NI KOLORUN O FOMO RERE
KE GBOBO EN TO NWOMO.

BIBI LA BIMO TUNTUN
EDUMARE JOMO TUNTUN O DAGBA
KOUN NAA O SI DOLOMO TUNTUN
KULUKULUKULU OMO WEERE
LODEDE GBOGBO WA.

ABOYUN NU KO BI TIBI TIRE
A KII GBEBI EWURE
A KII GBEBI AGUTAN
LOJO IKUNLE ABOYUN
KA GBOHUN IYA
KA GBOHUN OMO TITUN

WEREWERE LEWE NBO LARA IGI
GBEBE NII RO KOKO LAGBALA
A TABOYUN A TI KOKO
YIO ROYIN LORUN
GBEDEMUKE
GBEDEMUKE
                                        (AMIN OOOO)


EWI:OLOLUFE MI

                                         IFE-MI


Ota omi sowon laarin ota,
Otalenigba eye ni nbe nigbo, sugbon okin ni olori won,
Oto bi aye wunmi oko re so ni ife,
Ife ayanmo ati ori ko ni akawe.
Imule kole ife si origun merin aye,
Ikini nje adimula,
Ikeji nje majemu,
Iketa nje Akoja Ofin,
Ikerin nje ailopin,
Ife ti n pani ju oguro,
Ife ti n ro bi ojo,
Ife bi odo ti ko ni orisun,
Amoye ni tu oko adiitu ife.
Eji owuro mi ni,
Okan mi mu omi ife re,
Otun ku ni ibon ife dun,
Ibon ife wa ko le ku si ogun,
Afi ko bamidele.
Oju-oro ife wa leke omi,
Osi-bata ayanfe mi lefo so ri omi,
Mo subu lu apoto ifere afi ko tun mi mo,
Iwo lailai mi.
Irun wu apari,
Oro(wealth) wu ole,
Owu ki dahun'so,
Opele ki da difa,
Ori ki da la,
Oju ti elegan ni ijo ti isin ife wa la,
Elegan poun rere ekun nigbati orun ife wa ko lati wo.
ASEYI SAMODUN O. AMIN.
YOOBA DUN!

Monday, 24 April 2017

EWI:IWA OMOLUABI

''Ọmọluwabi,
Jẹjẹ ẹ lo nlọ,
Ọmọluwabi,
Jẹjẹ ẹ lo nbọ,
Ọmọluwabi,
Ẹmaṣe rii bi pe o gọ,
Ọmọluwabi,
Ọga(chameleon) to nyọ rin iku npa,
Ọmọluwabi,
Abelentase ọpọlọ to njanra ẹ mọlẹ,
Ọmọluwabi,
Ibi to dakẹ rọrọ ni Ọlọrun ngbe,
Ọmọluwabi,
Aimọye ẹgbin lo ngba mọra.''
Iwa jẹ iṣesi eniyan kan laarin awọn olubagbe rẹ. Bi iṣesi ẹni ba dara, awọn eniyan yoo maa pe oluwarẹ ni oniwa rere. Bi iṣesi oluwarẹ ko ba si bojumu, awọn eniyan yoo maa pe e ni oniwa buburu. Awọn ti iwa wọn ba dara ni Yooba npe ni ọmọluwabi eniyan.
Ohun ti Yooba gba pe o jẹ iwa ọmọluwabi pọ pupọ. O bẹrẹ lati ori kikini ti o fi de ori aajo eniyan ṣiṣe. Eyi ti a le sọ pe o jẹ ipilẹṣẹ iwa ọmọluwabi ni ikini. Yooba gba pe ẹni ti ko ba mọ eniyan ki ko yatọ si ilabiru baba ọbọ.
Lati igba ti ọmọ ba ti wa ni pinniṣin ni awọn obi rẹ yoo ti maa kọ ọ ni aṣa bi a ti nki eniyan. Ati ọmọde ati agba, ati ọba ati ijoye, ati olowo ati mẹkunnu ni o pọn dandan fun lati pa aṣa yii mọ ni ilẹ Yooba. Bi o ti ṣe pataki fun ẹni ti a nki pe ki o fi ọyaya dahun, bẹẹ naa ni o ṣe pataki fun ẹni ti n ki ni ki o fi ọyaya ki ni.
Yatọ si ikini ti a gba pe o jẹ ọpakuntẹlẹ(most) iwa ọmọluwabi ni ilẹ Yooba, ibọwọ fun agba tun jẹ ọkan gbogi. Bi eniyan ba fi ọjọ kan ju ẹlomiran lọ, ọwọ(respect) ọjọ kan naa yoo wa lara rẹ titi dọjọ ogbo wọn ni. Bi Yooba ba si sọ pe papanlagi tabi ipanle ni ẹnikan, aini ibọwọ fun agba pẹlu ohun ti wọn n tọka si lara rẹ.
Bi agbalagba ati ọmọde ba n jẹun pọ, o ni bi ọmọde ṣe gbọdọ jokoo, ki o le fi iwa irẹlẹ ati ibọwọ fun agba han. Yala ki o bọ itan akere tabi ki o na ẹsẹ gbọọrọ, ọmọde ko gbọdọ fẹ niwaju awọn agba; bẹẹ ni ko gbọdọ ṣaaju mu ẹran lawo. Okele bibu ati bi ọmọde ṣe n run ọbẹ gbọdọ fi itẹriba han.
Ọmọluwabi gbọdọ jẹ ẹni ti o nfi ara balẹ gba imọran ti agba ba fun un. Bi o ba si ṣẹ(err), ti wọn ba tọka si ẹṣẹ rẹ, o gbọdọ le tuuba(ask for forgiveness).
Yooba ka ẹni ti ki i ba ṣe nnkan wọnyi si olori kunkun eniyan, iru ẹni bẹẹ ki i ṣe ọmọluwabi rara.
Ohun kan pataki ti Yooba tun fi n mọ ọmọluwabi ni iwa itiju. Yooba gba pe ẹnikẹni ti ko ba ni itiju, ki i ṣe ọmọluwabi ati pe ko si arun ti ko si lara iru ẹni bẹẹ tan. Ẹni ti o ba ni itiju, ko ni jale, ko nii ṣeke, ko nii purọ, ko ni ja ajangbila, bẹẹ ni gbogbo iwa aibikita gbogbo iyoku ni ko ni i si lọwọ rẹ.
Riran ara ẹni lọwọ tun jẹ ọna kan ti a fi le mọ eniyan gẹgẹbi ọmọluwabi. Eyi ni pe ki a ma ni iwa anikan-jọpọn tabi iwa imọtara ẹni nikan(selfishness). Bi a ba ri ẹni ti o ku diẹ ki o to fun ti a si ṣe iranlọwọ fun iru eniyan bẹẹ, iwa ọmọluwabi ni a hu yẹn. Ọmọluwabi ko nii ba afọju lọna ko gba ọpa lọwọ rẹ; kaka bẹẹ, yoo baa di ọpa naa mu kọja de ibi ti ko ti nii ṣoro fun lati mọ ọna ni.
Ojuṣe gbogbo ọmọ Yooba ni lati jẹ ỌMỌLUWABI. Olodumare yoo fi rọwa lọrun lati ṣe. Amin.
Yooba Dun!
Oyin Ni!

Ewi: idagbere fun senator isiaka adetunji adeleke

                                     
  iku se ika,iku doro,iku mu eni ire lo
 iku ogba owo beni kogba obi tofi so ile ola di aworo
bi iku bada ojo ni,bi o ba da osu laye omo adarinrun oba ti mura sile laye
iku oda ojo beni koda osu to fi mu adetunji walo.

Ose, aise igi toto ki bawo pe ni igbo
awon eni rere ki bawo pe ni duniyan
gbigbo ti mo gbo pe adeleke ku
odu mi omi boloju mi,mo ni olore wa lo
akoni ninu awon oselu pakoda.

Eni ajo ji lowuro oni to tiwa dagbere faye pe odi igba ose
Ase igba tan bi orere ojo bawo tan lobi opa ibon
Iku wole logan loba mu baba walo
Ko gba owo beni ko gba agbo iku seka
Se oti wa tan nanu,se oti wa di o igbagbe na nu
Se otitu wa di ohun itan na nu, pe erin subu,
pe ajanaku si bi oke ,kole dide

serubawon ,odigbere, odi owuro,
Ipade tudi ojuola,otu di ari nako
otu bawo di oko alawo
otu  di iwaju ite eledumare oba ni bi ti ipinya ko ni si mo

odigba ooo akoni okunrin,odigba gomina alagbada akoko ni pinle osun
oluomo  odigba ose,gbogbo omo ede moku arogun se lede leyin re
gbogbo re omo se lede leyin re,gbogbo egbe olosusu owo se lede leyin re,
bobade ajule mo bawo je ekolo moje ohun oti wo baje lajule orun ni ko mo bawo je.
Sunre ooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooooo

Thursday, 20 April 2017

Ewi: Aje

           

        EWI:(AJE)
Ojumo moo peregede
Aje olokun asoro dayo
Oju okun onii buru titi koma lee fe leele
Awalawulu oju orun owu kooko
Iworan olokun abii ara le kooko bii ota

Bi kelebee ba bale afara yii eruku kitikiti
Dasowolu lawo alara
Aje ni moo pe loni oo
Funfun loju aje
Ara aje funfun

Aje  aje aje, ogun gun nu so
Aje jen ni lowo mo je ni lorun
Orisa bu aje osi,aje ni iya
Inu egbi laje gbe
Hun ti aje bawa leda gbirigbiri omo tito


Aje ogungunso  oniso iboji
Aje oni bugbe wa fi ile mi se ibugbe wa fi odede mi se afin
Loni ojo aje je ki fa ra yi ola kiko ere oko dele
Onise owo ki won ma rise
Onisowo maa rere oja
Oni ise ijoba onii sagbako

Lagbara eledumare ki aje ba si ode gbogbo wa oooo (amin ooo)

Ewi: isokan

                   
                     Ewi:isokan
Isokan lokun toso aye ro
Isokan lagba ninu ohun gbogbo
Isokan koni se nipa ile ti oti wa tabi eya ta tibi o
Okun ti kole ja hunbi isokan ni

Apero isokan ni ikan ni ti won fi mo ile
Apero isokan ni erun ni ti won fi mo agiyan
Apero isokan ni oyin ni ti won fi mo afara
Ewa eje kase rawa  losusu owo kase rawa lokan

Isokan lagba ohun ni ife se arole fun
Isokan lobi alaafia ti yoruba,igbo ati hausa nse gbe po ni ife aseitan
Isokan lomu ife aseitan wa laarin loko laya
Hun bi  ibi ti isokan ban gbe ibe ni ayo ohun alaafia nbe
Hun bi ibi isokan ba wa kosi gbekeyide nibe tutu niro koko lagba la hun bi isokan

Isokan lole mu  igbe aye gbadun fun gbogbo wa
Lagbaja pale ogun mo lakasegbe gberin mo ote hun bi isokan lo sonu laarin won
Emaje ka dalorun mo sapa,eje ki agba eri arawa je
Eje kasun kale fedo lori ororo ki igbadun ledeba mutumuwa
Isokan lowa larin isu to fi yoo omo ti ko gbagbe apari
Isokan lagbado ni to fi yoo tie lai gba gbe irukere
Isokan kana lowa larin omi ati iserun omi ti wo fi gbe po lalafia
                    
                         (isokan lagba ri gbogbo ebi oro)




Sunday, 16 April 2017

EWI: AFORITI

AFORITI LO LAYE
MOFE KI GBOGBO WA MO DAJUDAJUU
KI WURA TO DAN,OTI LANA KOJA
HUN BI ELEDUMARE LARO KADARA GBOGBO ENIYAN .

AFORITI NI ILA NI TIO FI KO
AFORITI NI AGBE NI OHUN OGBIN FITA
AFORITI LORO MO ADIE NI TIO FI DAKUKO
AFORITI KAN NAA NI IKAN NI TI O FI BAWON WEWE EJE.

RANTI PE AFORITI JAJU OHUN GBOGBO LO
AFORITI NI OMO IKOSE NI TI FI DOGA
AFORITI NI AKEEKO NI TO FI YEGE
RANTI TITA RIRO LAA KOLA
TOBA JINA TAN NI SOJU REKETE..

AFORITI NI ONISOWO NI TI AJE FI ILERE SE IBUGBE TI FI ODEDE RE SE AFIN
AFORITI LALA BARA MEJI NI TI FI RU ARUSO TI AFI PE NI IYA IBEJI
AFORITI NI LOGEDE NI TIO FI WO KOKO YE
AFORITI NI ORI NI TIO FI SE ATUKUN ARA
AFORITI NI AHUN  TI FI SE ORE EYIN LADURU AGARA TO DA.

AFORITI NI EWURO NI TO FI JE AGBA IGI
AFORITI NI KAHUN NI TO FI  JOBA LARIN EGBERUN OKUTA
AFORITI NI GBENI DE IPO OLA TI TU SONI DI ENI IYI LAWUJO
AFORITI NIMU OHUN GBOGBO SEREGI TIFI JORAWO.