EWI:(AJE)
Ojumo moo
peregede
Aje olokun
asoro dayo
Oju okun
onii buru titi koma lee fe leele
Awalawulu
oju orun owu kooko
Iworan
olokun abii ara le kooko bii ota
Bi kelebee
ba bale afara yii eruku kitikiti
Dasowolu
lawo alara
Aje ni moo
pe loni oo
Funfun loju
aje
Ara aje
funfun
Aje aje aje, ogun gun nu so
Aje jen ni
lowo mo je ni lorun
Orisa bu aje
osi,aje ni iya
Inu egbi
laje gbe
Hun ti aje
bawa leda gbirigbiri omo tito
Aje
ogungunso oniso iboji
Aje oni
bugbe wa fi ile mi se ibugbe wa fi odede mi se afin
Loni ojo aje
je ki fa ra yi ola kiko ere oko dele
Onise owo ki
won ma rise
Onisowo maa
rere oja
Oni ise
ijoba onii sagbako
Lagbara
eledumare ki aje ba si ode gbogbo wa oooo (amin ooo)
0 comments:
Post a Comment