Monday, 24 April 2017

EWI:IWA OMOLUABI

''Ọmọluwabi,
Jẹjẹ ẹ lo nlọ,
Ọmọluwabi,
Jẹjẹ ẹ lo nbọ,
Ọmọluwabi,
Ẹmaṣe rii bi pe o gọ,
Ọmọluwabi,
Ọga(chameleon) to nyọ rin iku npa,
Ọmọluwabi,
Abelentase ọpọlọ to njanra ẹ mọlẹ,
Ọmọluwabi,
Ibi to dakẹ rọrọ ni Ọlọrun ngbe,
Ọmọluwabi,
Aimọye ẹgbin lo ngba mọra.''
Iwa jẹ iṣesi eniyan kan laarin awọn olubagbe rẹ. Bi iṣesi ẹni ba dara, awọn eniyan yoo maa pe oluwarẹ ni oniwa rere. Bi iṣesi oluwarẹ ko ba si bojumu, awọn eniyan yoo maa pe e ni oniwa buburu. Awọn ti iwa wọn ba dara ni Yooba npe ni ọmọluwabi eniyan.
Ohun ti Yooba gba pe o jẹ iwa ọmọluwabi pọ pupọ. O bẹrẹ lati ori kikini ti o fi de ori aajo eniyan ṣiṣe. Eyi ti a le sọ pe o jẹ ipilẹṣẹ iwa ọmọluwabi ni ikini. Yooba gba pe ẹni ti ko ba mọ eniyan ki ko yatọ si ilabiru baba ọbọ.
Lati igba ti ọmọ ba ti wa ni pinniṣin ni awọn obi rẹ yoo ti maa kọ ọ ni aṣa bi a ti nki eniyan. Ati ọmọde ati agba, ati ọba ati ijoye, ati olowo ati mẹkunnu ni o pọn dandan fun lati pa aṣa yii mọ ni ilẹ Yooba. Bi o ti ṣe pataki fun ẹni ti a nki pe ki o fi ọyaya dahun, bẹẹ naa ni o ṣe pataki fun ẹni ti n ki ni ki o fi ọyaya ki ni.
Yatọ si ikini ti a gba pe o jẹ ọpakuntẹlẹ(most) iwa ọmọluwabi ni ilẹ Yooba, ibọwọ fun agba tun jẹ ọkan gbogi. Bi eniyan ba fi ọjọ kan ju ẹlomiran lọ, ọwọ(respect) ọjọ kan naa yoo wa lara rẹ titi dọjọ ogbo wọn ni. Bi Yooba ba si sọ pe papanlagi tabi ipanle ni ẹnikan, aini ibọwọ fun agba pẹlu ohun ti wọn n tọka si lara rẹ.
Bi agbalagba ati ọmọde ba n jẹun pọ, o ni bi ọmọde ṣe gbọdọ jokoo, ki o le fi iwa irẹlẹ ati ibọwọ fun agba han. Yala ki o bọ itan akere tabi ki o na ẹsẹ gbọọrọ, ọmọde ko gbọdọ fẹ niwaju awọn agba; bẹẹ ni ko gbọdọ ṣaaju mu ẹran lawo. Okele bibu ati bi ọmọde ṣe n run ọbẹ gbọdọ fi itẹriba han.
Ọmọluwabi gbọdọ jẹ ẹni ti o nfi ara balẹ gba imọran ti agba ba fun un. Bi o ba si ṣẹ(err), ti wọn ba tọka si ẹṣẹ rẹ, o gbọdọ le tuuba(ask for forgiveness).
Yooba ka ẹni ti ki i ba ṣe nnkan wọnyi si olori kunkun eniyan, iru ẹni bẹẹ ki i ṣe ọmọluwabi rara.
Ohun kan pataki ti Yooba tun fi n mọ ọmọluwabi ni iwa itiju. Yooba gba pe ẹnikẹni ti ko ba ni itiju, ki i ṣe ọmọluwabi ati pe ko si arun ti ko si lara iru ẹni bẹẹ tan. Ẹni ti o ba ni itiju, ko ni jale, ko nii ṣeke, ko nii purọ, ko ni ja ajangbila, bẹẹ ni gbogbo iwa aibikita gbogbo iyoku ni ko ni i si lọwọ rẹ.
Riran ara ẹni lọwọ tun jẹ ọna kan ti a fi le mọ eniyan gẹgẹbi ọmọluwabi. Eyi ni pe ki a ma ni iwa anikan-jọpọn tabi iwa imọtara ẹni nikan(selfishness). Bi a ba ri ẹni ti o ku diẹ ki o to fun ti a si ṣe iranlọwọ fun iru eniyan bẹẹ, iwa ọmọluwabi ni a hu yẹn. Ọmọluwabi ko nii ba afọju lọna ko gba ọpa lọwọ rẹ; kaka bẹẹ, yoo baa di ọpa naa mu kọja de ibi ti ko ti nii ṣoro fun lati mọ ọna ni.
Ojuṣe gbogbo ọmọ Yooba ni lati jẹ ỌMỌLUWABI. Olodumare yoo fi rọwa lọrun lati ṣe. Amin.
Yooba Dun!
Oyin Ni!

1 comments:

Ewi:Iwa Omoluabi ~ Asa-Tiwatiwa >>>>> Download Now

>>>>> Download Full

Ewi:Iwa Omoluabi ~ Asa-Tiwatiwa >>>>> Download LINK

>>>>> Download Now

Ewi:Iwa Omoluabi ~ Asa-Tiwatiwa >>>>> Download Full

>>>>> Download LINK

Post a Comment