Tuesday 25 April 2017

ITAN ORILE: ILE-IFE

                                             (ITAN ORIRUN YORUBA)


Bi mo so lana iwadi nlo lowo nipa itan Ile Ife saaju ki Odua to de. Nigbati Odua de si Ile Ife o ba awon enia nibe Obatala sini olori won, iwadi je ka mo pe Obatala funrare naa je alejo sugbon o ti pe nibe ki Odua to de. Nigbati Obatala ri Odua papa to tun wa je enia funfun inu re o dun sugbon pelu gbogbo enia ti Odua ko wole Ile Ife kosi ohun to le se, Odua je enia to ga dada to iwon ese bata mewa si mokanla o si sigbonle wale be. Awon enia to ba ni Ile Ife ki i ga rara won o ga ju ese bata merin abo si marun lo eyi je ki won mo wari fun awon Odua bi abami enia, iran Odua ti wa tipe nile Arabu lati ibe ni won ti wa Egypt ati Ethopia ki won to wa wa si Sudan lati Sudan ni Odua ti wa si Ile Ife, Yariba ni oruko eya Odua nje awon eya Yariba si wa ni awon orilede meteta yi di oni. Yariba yi lo wa di Yoruba loni sugbon nigba lailai eje Oranmiyan nikan lo nje Yoruba kiise gbogbo awa omo Odua lo nje be. Odun 1919 ni awon Oibo ni ki gbogbo omo Odua mo je oruko kan soso. Opo ogun ni Odua ja to si gba ile pupo eyi wa je ki awon ara Ile Ife mo bu owo fun bi won se fi je Oba niyi, ko pe ti won fi Odua je Oba tan ni awon omo re bere si ni ku akoko o koko ro si Obatala sugbon nigbati Obatala wa ba kedun to si je ko mo pe iru re naa ti se oun naa ri idi niyi ti awon omo oun o fi gbe ni Ile Ife, bayi ni Odua se pe awon alayewo ninu awon to mu lehin, won wa je ko mo pe ila to nko fun awon omo re lo fa, bayi ni Odua se da ila kiko duro gbogbo awon omo to ti ko ila fun lo ku tan ko to wa bi OKanbi. Itan je ka mo pe nigba aye Odua ni ilu Binin ni ipinle Edo ti wa labe Ile Ife. Iwadi je ka mo pe nigbati awon egbon Odua gba esin Islam ni ilu Bornu won wa fi Alfa kan ranse si Odua lati le gba Islam sugbon Odua ati awon ara ile Ile Ife ko esin yi. Lehin odun die oda ba bere ojo ko ko ro mo gbogbo ebo ati etutu ni won sibe pabo ni.
(nje o ti gbo eyi ri bi)

0 comments:

Post a Comment