Ibadan mesi Ogo, nile Oluyole.
Ilu Ogunmola, olodogbo keri loju ogun.
Ilu Ibikunle alagbala jaya-jaya. Ilu Ajayi,
o gbori Efon se filafila. Ilu Latosa, Aare-ona kakanfo.
Ibadan Omo ajoro sun.
Omo a je Igbin yoo,fi ikarahun fo ri mu.
Ibadan maja-maja bii tojo kin-in-ni,
eyi too ja aladuugbo gbogbo logun,
Ibadan ki ba ni s’ore ai mu ni lo s’ogun.
Ibadan Kure! Ibadan beere ki o too wo o,
Ni bi Olè gbe n jare Olohun.
B’Ibadan ti n gbonile bee lo n gba Ajoji.
Eleyele lomi ti teru-tomo ‘Layipo n mu.
Asejire lomi abumu-buwe nile Ibadan. A ki waye
ka maa larun kan lara, Ija igboro larun Ibadan.
0 comments:
Post a Comment